ÌDÍJE ÀTẸ́LẸWỌ́ FÚN Ẹ̀BÙN LÍTÍRÉSỌ̀ YORÙBÁ TI ỌDÚN OGÚN OGÚN ÀRÚN

ÀTẸ́LẸWỌ́ jẹ́ ẹgbẹ́ tí a dá sílẹ̀ ni ọjọ́ kiní oṣù kẹfà, ọdún 2017 gẹ́gẹ́ bi ojútùú láti kọjú oríṣiríṣi àwọn ìpèníjà tó n d’ojukọ èdè àti àṣà Yorùbá. Yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyan ni kò mọ̀’kọ mọ̀’kà ní èdè abínibí wọn, ó tún ṣe ni láàánú pé àwọn ìwé lítírésọ̀ Yorùbá tó jọjú kò wọ́pọ̀ mọ́n. Eléyìí sì ń ṣe àkóbá fún ipa wa láti dásí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń lọ lágbáyé pẹ̀lú òye abínibí wa.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó dé láti yí ǹkan padà, ÀTẸ́LẸWỌ́ wá láti ṣe àtúntò àti ìgbélárugẹ èdè àti àṣà Yorùbá pẹ̀lú àwọn àfojúsùn wọ̀nyìí:

Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àfojúsùn wa, ÀTẸ́LẸWỌ́ fi àsìkò yìí kéde Ìdíje Ẹ̀bun Ọdọọdún Fún Lítírésọ̀ Yorùbá. Ìdíje yìí wà fún gbogbo àwọn òǹkọ̀wé èdè Yorùbá ti wọn ò tí tẹ iṣẹ́ (ewì, eré oníṣe àti àròsọ) wọn jáde rí. À ń fi ìdíje yìí lọ́lẹ̀ ní ìgbà karùn-ún, èyí sì jẹ́ àgbékalẹ̀ pàtàkì láti ṣe ayẹyẹ yìí.

A gbé Ìdíje yìí kalẹ̀ láti le kojú oríṣiríṣi ìpèníjà tó ń kojú ìwé kíkọ ní èdè Yorùbá bíi rírí àwọn atẹ̀wéjáde to mú’ṣẹ́ wọn lọkúnkúndùn, ìwé títà oun níní àwọn olùkàwé to ní ìfarajìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìdíje yìí tún gbèrò láti dá ògo àṣà lítírésọ̀ Yorùbá padà, eléyìí tí ọ̀pọ̀ èèyan ti ṣe sàdáńkatà fún jákèjádò àgbáyé tẹ́lẹ̀rí.

Ìlànà

Fún àwọn tí wọ́n bá nífẹ sí fífi iṣẹ́ wọn ráńṣẹ́ sí ìdíje ÀTẸ́LẸWỌ́, wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé àwọn ìlànà wọ̀yìí:

Àtẹ́lẹwọ́ ní àṣẹ láti má ka ìfiránṣẹ́ tí kò bá tẹ́lẹ̀ àwọn ìlànà òkè yìí. A sì ní àṣẹ láti wọ́gi le ìfiránṣẹ́ náà.

Gbèǹdeke

A kò ni ka iṣẹ́ ti ó bá wọ’le lẹ́yìn Ọjọ́ keje, Oṣù Kẹta, Ọdún 2025

Àwọn Olùdájọ́

Ó ń bọ̀ lọ́nà

Ẹ̀bùn

A ó ṣí’ṣọ lójú eégún olùdíje kan ṣoṣo tó gbégbá orókè. Olùdíje yìí yóò jẹ ẹ̀bùn Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Kan Náírà (N1,000,000) àti àǹfàní láti tẹ ìwé náà jáde. Pẹ̀lú òfin àti ìlànà wa.

Ìwádìí

Fún ìwádìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìbáṣepọ̀

Ìfiránṣẹ́

Ẹ wo línkì yìí láti fi iṣẹ́ yín ránṣẹ́ sí wa. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fi iṣẹ́ rẹ̀ ṣọwọ́ sí méélì wa.

Àwọn tí iṣẹ́ wọn tayọ 2021 - 2024

  1. Ṣeun Adéjàre (T’ẹníkú Ló gbé)
  2. Amos Ọlátúnjí Pópóọlá (Akínkanjú Ọdẹ Nínú Igbó Àmọ̀tẹ́kùn)
  3. Sodiq Lawal (Koówè Ń kéé (Àròjinlẹ̀ Àròfọ̀))
  4. Agboọlá Àyándìran (Ó Já Sọ́pẹ́)
  5. Mustapha Sheriff (Akọdan) – Olùgbégbá Orókè
  1. Waliyullah Tunde Abiimbola (Oko Ẹranko, a Yorùbá translation of George Orwell’s “Animal Farm”). Olùgbégbá Orókè
  2. Kafilah Ayọ̀bámi Fashola (Àbẹ̀ní)
  3. Bákárè Wahab Táíwò (Atewolara Akewi-Akowe)
  4. Anífowóṣe Zainab Olúwafúnmilọ́lá (Igbeyin Owuro)
  5. Abdulkareem Jeleel Ọlasunkanmi (Ewì Kòbọmọjẹ́)
  1. Babátúndé A.  Shittu (Láàdì) Olùgbégbá Orókè
  2. Jimoh Lateef Adérójú (Àròfọ̀ Àsìkò)
  3. Álímì – Adéníran O̩mo̩s̩aléwá (Àwọn Obìnrin Òwu, a translation of Women of Owu by Femi Osofisan)
  4. Rasheed Malik Adeniyi (Nǹkán Yán)
  1. Adéwùmí Fatimah Luqman (Ọ̀rẹ́ Àtàtà) Olùgbégbá Orókè
  2.  Fámúyiwa Olúwafẹ́mi (Àtẹ̀yìntọ̀)
  3. Abdulrosheed Ọlálékan Fádípẹ̀  (“Àwọn Arìnrìn Àjọ̀ Àkọ́kọ́ Sínú Òṣùpá”, a translation of “The First Men in the Moon” by H.G Wells)
  4. Adémọ́lá Ọláyíwọlá (Ewì Àrìnyè)

Nínú Ìròyìn

2021
2022
2023
2024

Láti ọwọ́ọ Àtẹ́lẹwọ́

Scroll to Top